Ọ̀nìyọ̀n Lásọ́n

Ẹ̀wẹ̀n gbọ́ owùn mi néréùn Ìjẹ̀bú, eréùn wèé rìí yùn, èdè yíyùn rèé, ẹ gbọ́ owùn mi


Ùwọ jáde


Ùwọ jáde nátọkàn mí

Éè súrun náyé mi rìí ḿ lè ṣe

Ojú ẹ wà nọ́kàn mi, ọ̀ọ̀yọ̀n wèé

Bí éè sọ́kùnrẹn mìírẹ̀n nálẹ̀de ká wà wèé

Nígbà kí m bá sù

Màá jí rójú ẹ nérò mí

Irọn ẹ, ẹrun ẹ, ara ẹ

Jáde nátèrò mi, ẹ jọ̀ọ́

Mo fẹ́ nẹ́ ọ̀wọn èrò mìírẹ̀n

Kí m bá lè nẹ́ wọn

Mo mọ̀ fọ ara yíyùn kẹ́ nẹ́

Ṣùgbọ́n, mí ì fẹ́ ẹ mọ́

Wo lọ nátèrò mi, ẹ jáde kíá

Ùwọ jáde



Ùwọ ti bẹ̀rẹ̀


Ùwọ ti bẹ̀rẹ̀

Ṣé wo mọ̀ ọ́n?

Wíwò ré

Ùwọ ti bẹ̀rẹ̀

Mí ì mọ orúkọ ẹ

Mí ì mọ irunkírun nípa ùwà ẹ

Ṣùgbọ́n, mo mọ̀ fọ ojú ẹ máa ḿ wò mí

Kúdìí kó o mí ṣe é? Ẹ sọ fún mi

Mò mí wá ùdí yẹn

Mo rí ẹ, irọn ẹ

Dede urun kí wo nẹ́

Ùbírọ̀ mi ré,

Ṣé wo nẹ́fẹ̀ẹ́ fún mi?