Ayé Tó Dára Sí Wa
A máa gbádùn láyé tá wà yìí nígbà tá bá sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìyanú tó ṣe fún wa
Ẹ̀pẹ́
Ìbàdàn
Ọ̀yọ́
Èkó
Ayé lẹ́wà wa
Àwa máa ń wò bí ìgalà máa ń fò lórí koríko
Ó rẹ́wà gan-an, ọkàn wa máa tètè kún pẹ̀lú ìfẹ́ fún wọn
Àwa máa kẹ́ fún wọn bí a máa ń kẹ́ ọmọ wa
Ìkẹ́ wà
Ìkẹ́ wá
Àwa máa ń wò bí òṣùpá máa ń là
Ó là, ó là yaranyaran tí gbogbo ayé lè rí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn yòò
Àwa máa lálàá lórí rẹ̀, ẹwà rẹ̀ kò lè lọ lát’ọkàn wa, láti èrò wa
Ẹwà wà
Ẹwà wá
Àwa máa ń wò bí agbára àyànfẹ́ wa yí wa ká
Ó yí wa ká, apá àyànfẹ́ wa máa mọ́ra wa yán-ányán-án
Àwa kò lè ronú ńpa irú ìfẹ́ òdodo tàyànfẹ́ wa ní fún wa
Ìfẹ́ wà
Ìfẹ́ wá
Àwa máa ń wò bí èèyàn máa ṣàánú ọ̀tá wọn
Ó dára gan-an, iṣẹ́ ìyanú nìyẹn, láti ìkórìíra sí ìdáríjì pátá
Àwa máa gbàgbọ́ pé ìfẹ́ láti ọkàn tẹni lè ní, ó lè wà, àlàáfíà lè wà
Àánú wà
Àánú wá
Bí ìgalà máa ń fò, òṣùmàrè máa jáde
Bí òṣùpá máa ń là, ìbùkún máa bá sórí rẹ̀
Bí agbára àyànfẹ́ wa máa ń yí wa ká, ire máa wà
Bí èèyàn máa ń ṣe àánú, ìṣẹ́gun máa dé
Ó le láti mọ̀ táyé wa bá dára sí wa
Àmọ́, a lè retí fún ayé kan tó dára
Àwa lè tan ìwà ọmọlúàbí wa kálẹ̀
Torí pé ayé wa dára, ó lẹ́wà, ó sì jẹ́ tiwa
Ké
Aláìbànújẹ́ ké látòkè tó ga nípa ayọ̀ rẹ
Bí ó yí ẹ ká nínú ìjì ìkórìíra, ìbínú má bà ẹ́ jẹ́
Akélátòkè ké ooo, ké kó yó, kò sí ìkórìíra tara rẹ mọ́
Ìmọ́lẹ̀ látọkàn rẹ, ó ràn yanranyanran bí ọ̀run tódáyé ti ṣèdá
Akénígbó ké ooo, ké látẹnu rẹ bí ayọ̀ ti padà wá sáyé rẹ
Kíké lo níláti ké, kò níláti jẹ́ ẹnikẹ́ni tí ò mọ̀ nípa ìṣẹ́gun rẹ
Onírelé relé, lọ sílé rẹ, ìwọ lo máa sọ fún ará ilé ẹ bí o ti tun ayé ẹ bẹ̀rẹ̀