Ǹjẹ́ Ìfẹ́ Ni?

Àwọn ewì ní báyìí jẹ́ ewì nípa ìfẹ́ tọkàntọkàn tí ẹni máa ń ní sáyànfẹ́ wọn

Ìkọ̀wé Kan


Ìwọ kò lọ láti ọkàn mi

Ìwọ, ojú rẹ kò lọ láti orí mi, láti ìrántí mi

Mo ti ní ìfẹ́ fún ẹ tẹ́lẹ̀

Ṣùgbọ́n, ojú rẹ kò lọ

Màá sùn, màá jí

Ojú rẹ máa wà níbẹ̀

Ara ńlá rẹ mo máa ń lá nípa ẹ

Àlá ńlá ṣe mò ń lá lórí ìwọ

Mo mọ̀ pé o ti lọ

Ṣùgbọ́n, o ò lọ láti ẹ̀mí mi

Mo fẹ́ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹ

Mi ò lè ṣe é

Ẹ̀rù máa ń ba inú mi jẹ́

Ìwọ kò lọ láti ayé mi

Mo máa ń kọ ewì nípa ìfẹ́ mi fún ẹ

Mo máa ń kọ bí o ti máa ń wò mí

Bí a ti ṣe ń wò ara wa lójoojúmọ́

Mo mọ̀ pé ẹ jẹ́ òyìnbó, ṣùgbọ́n

F'etí gbọ́ mi, oyin mi ni ìwọ

Oyin dídùn mi 

Àyànfẹ́ mi láti lọ́hùn-ún ni ìwọ

Mo mọ̀ pé màá sọ “ẹ káàárọ̀” sí ẹ, ọjọ́ kan



Ajá


Ọkọ mi, má ṣe bí ajá


Má ṣe bí ajá, má ṣe bí ajá

Ó sá bí ẹni tó ò ní orí lára rẹ̀


Má ṣe bí ajá, má ṣe bí ajá

Kò gbọ́ ohùn tẹ́nikẹ́ni máa ń sọ


Má ṣe bí ajá, má ṣe bí ajá

Má lọ káàkiri bí ajá máa ń ṣe


Má ṣe bí ajá, má ṣe bí ajá

Ajá wèrè náà fẹ́ lọ sí ibùsùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ alẹ́ dé alẹ́


Má ṣe bí ajá, má ṣe bí ajá

Ó gbó, “gbó, gbó, gbó,” látàárọ̀ d'alẹ́



Má ṣe bí ajá, má ṣe bí ajá

Má mí bí ajá máa ń mí hẹlẹhẹlẹ


Má ṣe bí ajá, má ṣe bí ajá

Aláìgbọ́ràn bí ewúrẹ́ ni


Má ṣe bí ajá, má ṣe bí ajá

Ajá tó lè jẹ ẹran èèyàn bí akátá


Ẹ jọ̀ọ́, ọkọ mi, má ṣe bí ajá

O jẹ́ ẹni tọ́kàn mi ti yàn


Má yá wèrè bí ajá, àyànfẹ́ mi

Má ṣe bí ajá, má ṣe bí ajá

Tèmi Ni Ìwọ


Ìwọ jẹ́ ti èmi

Ìwọ ìràwọ̀ mi


Má fi mi sílẹ̀

Lórí ilẹ̀ ńlẹ̀



Tọ́jú ẹ̀mí mi

Àyànfẹ́ mi mí ẹ̀mí mi


Oyin mi

Oyin dídùn mi



Fetí gbọ́ mi

Dúró pẹ̀lú mi


Tímọ́lẹ̀ ẹ bá tàn

Kò sẹ́ni tó lè pa á



Má lọ, má í lọ

Pẹ̀lú ẹ mo fẹ́ wà


Tèmi jẹ́ ìwọ

Ìràwọ mi ni ìwọ