Ẹ Máa Gbọ́
Ẹ gbọ́ ohùn mi, mo fẹ́ sọ̀rọ̀
Fi wá sílẹ̀
Wọn máa ń sọ
Ká gbọ́dọ̀ gbéyàwó sílé
Nígbà tá ò bá fẹ́ ìyàwó rárá
Wọn máa ń sọ pé
Ká gbọ́dọ̀ jẹ́ bàbá tọmọ
Àmọ́, ṣé wọn rò nípa ọmọ tó ò lóbí nǹkan kan?
Wọn máa ń sọ pé
Kò jẹ́ nǹkan ti ọmọlúàbí máa ń ṣe
Sùgbọ́n, ṣe é kàn ọ́?
Ayé mi jẹ́ tèmi, ayé ẹ jẹ́ ti ẹ
Wọn máa ń sọ pé
Sùgbọ́n, ọlọ́run ti sọ wí pé…
Màá jẹ: ọlọ́run kò kàn mí, bí ìgbé ayé mi kò kàn ẹ́
Wọn máa ń béèrè pé
Ṣé ẹ nífẹ̀ẹ́ fún ara yín?
Màá dá wọn lóhùn: Ṣé ẹ mọ̀ kí nífẹ̀ẹ́ jẹ́?
Bọ́kùnrin bá bọ́kùnrin sùn
Ìfẹ́ wà
Bóbinrìn bá bóbinrìn sùn
Ìfẹ́ wà
Tá bá dòbí
Tó bá ṣe pé jẹ́ òbí wù wá
A máa ṣe é, a máa tọ́jú ọmọ yẹn tí ò ní nǹkan
Tí ò mọ ìfẹ́ látọkàn téèyàn
Bọ́mọ, bọ́mọ káàkiri
A á gbọ́dọ̀ ṣe é
Gbé láyé yín
Bí a máa gbé láyé wa
Tẹ́ ò bá fẹ́ ara wa
Ìrànlọ́wọ́ ẹ
Kò lè ṣe nǹkan kan fún wa
A mọ ara wa,
Ṣé ẹ mọ ara ẹ?
Ẹnikẹ́ni tẹ́ fẹ́ bá ara wọn sùn, gun wọn
Bá máa gun ẹni tó wù wá
Ẹ jọ̀ọ́, fi wá sílẹ̀.
Mo nífẹ̀ẹ́ fún ẹ
Mo nífẹ̀ẹ́ fún ẹ
Pẹ̀lú bí ẹ máa ń ṣe nǹkan rẹ.
Bí o ṣe rìn lórí títì,
bí o ṣe sọ ọ̀rọ̀ rẹ,
bí o ṣe wò mí lójoojúmọ́,
bí o ṣe jẹ́ bí ọmọ ayé yìí.
Ọkùnrin méjì, papọ̀,
ìwọ pẹ̀lú mi, ìfẹ́ mi.
Mo ti gbọ́ àwọn ènìyàn
tí sọ pé,
"àwọn ọkùnrin papọ̀,
ó jẹ́ nǹkan tó burú, kò tó pẹ̀lú àwọn èrò tọlọ́run wa."
Mo gbọ́dọ̀ sọ sí ọlọ́run tí ayé wa,
ẹ pẹ̀lẹ́,
nítorí pé
kò séèyàn láyé tá wà yìí
tó lè sọ pé mi ó lè wà pẹ̀lú ọkùnrin kan,
ọkùnrin náà tí mo fẹ́.
Nítorí náà,
màá jà gidi gan-an ni,
pẹ̀lú gbogbo mo ní láyé yìí
fún ẹ,
ìfẹ́ mi,
ayọ̀ mi,
adé mi,
ọkọ mi.
Nítorí pé,
mo nífẹ̀ẹ́ fún ẹ.