E darapo mo wa lori Telegram
Ajihinrere Tim Bólúwatifẹ́ Òjó jẹ́ ẹni tí a rán ní iṣẹ́ ìpolongo ògidì ọ̀rọ̀ náà rán sí gbogbo àgbáyé. Awon ni olùdásílẹ̀ ile-isẹ ìránṣẹ́ Tim Boluwatife Global Outreach àti olùṣọ àgùntàn ijo Royal House Church ni Ìpínlẹ̀ Èkìtì, ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ẹ̀kọ́ Bíbélì jẹ́ ètò ìkọ́ni èdè Yorùbá labẹ́ asia ile-iṣẹ́ ìránṣẹ́ Revealing Jesus Ministries tí Ajihinrere Tim Bólúwatifẹ́ Òjó jẹ́ olùdarí rẹ̀.
Iṣẹ́ ìránṣẹ́ Ẹ̀kọ́ Bíbélì ni èdè Yorùbá yìí bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2017 láti wàásù ihinrere Kristi ati láti kọ awọn ọmọ Ọlọ́run ni ogidi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Èròngbà wa ni láti fi ìdí àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run múlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, kaakiri gbogbo ibi ti won ti nsọ èdè Yorùbá ní gbogbo àgbáyé.