Lati ọjọ kinni, oṣu kini ọdun 2020 ni a bẹrẹ akanṣe ẹkọ ọrọ Ọlọrun olojoojumọ fun idagbasoke awọn ọmọ Ọlọrun ninu ẹmi.
Ninu ẹkọ yii, ẹ o ri idahun si orisirisi ibeere, alaye kikun nipa orisun aisan, ife Olorun fun eniyan, bi eniyan se le ri iwosan gba nipa agbara Olorun, bi a se le ran awon to n saisan lowo lati gba iwosan ti won nilo abbl.
Ma beru! Ma foya! Bibeli wipe a ko tun gba emi eru láti maa beru mo. Gbogbo omo Olorun ni akikanju omo, sugbon bawo ni otito Oro Olorun yii se le farahan ninu aye wa. Teti si eko yii láti gbo nipa re.
Kini Oro Olorun so nipa Kadara, ayanmo, akunleyan abbl? Otito pombele láti inu Bibeli ni ẹ o ri ninu eko yii.
Kini Bibeli so nipa bi o se ye fun omo Olorun lati maa soro? Nje agbara kankan tile mbe ninu ahon bi? Bi o ba wa, bawo lo se ye ki a maa lo o? Alaye kikun wa ninu eko yii.
Ona to ga julo ti Olorun Alagbara fi n ba gbogbo awon omo Re soro ni nipa Oro Re ninu Bibeli. Leyin naa ni itoni atinuwa lati odo Emi Mimo. Ki wa ni ojuse ala ati iran ninu igbesiaye wa, ati pe kinni iha ti o ye ki onigbagbo ko si iran ati ala re? E fi ara bale gbo alaye kikun ninu eko yii.
Opolopo orin lonii ni awon omo Olorun nko, sugbon ti ko ba oro Olorun mu rara. Bawo ni a se le mo orin to bu iyi fun Jesu Oluwa, ati wipe kinni iyato laarin orin emi ati orin idaraya. E daanlodu eko yii lati gba idahun si awon ibeere yii.
Dafidi Oba je Wolii Olorun. Alaye kikun lori Orin Dafidi, orin iketalelogun (Psalm 23) ni eko yii je.
Agbara ajinde Jesu Oluwa lo bi Ijo Olorun. Kinni eredi ti ijo yii fi wa laaye lonii, ati wipe kinni awon ami idanimo fun Ijo Olorun Alaye? Kinni ipinu Olorun fun Ijo Re ninu aye lonii? Ekunrere alaye wa ninu eko yii.
Pataki ifedefo ninu igbe aye omo Olorun
Ekunrere alaye lori Eso Emi Mimo Olorun ti o wa fun gbogbo Kristeni.
Òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wípé kò sí ọmọ Ọlọ́run kankan tí yóò ṣègbé tàbí lọ sí ọ̀run àpáàdì. Kíni yóò wa ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ìdájọ́? Ẹ̀kọ́ yìí tan ìmọ́lẹ̀ sí eleyii lopolopo
O seese ki eniyan ti di eni igbala fun opolopo odun sugbon ki eniyan je alailoye nipa oun ti igbala je. Oun gbogbo ti Bibeli so nipa igbala alailegbe ati ainipekun ti iku ati ajinde Jesu Oluwa pese fun gbogbo eniyan ni eko yii je.
Eko yii je alaaye ipinnu Olorun fun awon obinrin lati atetekose. Bakannaa, a salaye ipo awon obinrin ninu ijo, ninu igbeyawo, lawujo abbl. A tun dahun awon ibeere lori oun ti Bibeli so nipa imura awon obinrin ati ori bibo. Eko yii se pataki fun gbogbo awa omo Olorun, l'okunrin l'obinrin wa.
Bi o tile je wipe Baba kan, Oluwa kan, Emi Mimo kan, igbagbo kan, baptismu kan ni gbogbo Kristeni lagbaaye ni, awon kan wa ti Olorun ti fun ni oore-ofe lati je ebun fun ijo Re. Alaye kikun lori ise-iranse ati ojuse awon aposteli, wolii, efangelisti/ajihinrere, olusoaguntan ati olukoni ni eko yii je.
Ise iranse iwaasu ihinrere fun awon ti ko ni Jesu je ise ti gbogbo omo Olorun ti gba logan ti a di eni igbala.
Ona to ga julo ti satani maa n lo lati fi awon eniyan sinu ide ni ERU. Sugbon isegun kan wa fun gbogbo omo Olorun lori satani ati awon omo ogun re.
Kini ojuse awe ninu adura? Nje awe je ona lati mu ki Olorun gbo wa ni kiakia bi? Oun ti awe ati adura je labe majemu laelae ati majemu tuntun ni a salaye ninu eko yii
Kiise gbogbo adura ti o wa ninu Bibeli ni o wa fun awa lonii. Idi eyi niwipe majemu tuntun yato fun majemu laelale (atijo). Awon adura majemu tuntun ni eko yii tan imole si
Ayo ayeyeraye ni ayo igbala ti Jesu fi fun wa. Ife inu Olorun si ni fun wa lati maa yo nigbagbogbo.
Gbogbo onigbagbo loni anfaani lati gba idari ati itoni Emi Mimo Olorun lai pe Wolii tabi iranse Olorun kankan. Eko yii je alaye lekunrere nipa bi Olorun se ndari gbogbo onigbagbo nipa Emi Mimo Re.
Kinni ese si Emi Mimo? Nje onigbagbo le se ese ti Jesu Oluwa ni ko si idariji fun yii?
Ilara, ibinu, igbesan ati beebeelo je awon ise ti ara ti ife Ọlọrun ninu wa ti fa tu. Ẹkọ yii tan imole si bi a se le maa rin ninu ife Ọlọrun to wa ninu okan wa.
Eredi ti a fi n pe awa Kristeni ni onigbagbo ni wipe a ni igbagbo. Ninu ẹkọ yii, ao ko bi a se le lo igbagbo wa lati ri ise iyanu Ọlọrun ninu aye wa.
Gbogbo ẹbun mẹsan ti Paulu Aposteli mẹnuba ninu Iwe Kọrinti Kinni ori kejila wa fun gbogbo onigbagbọ. Alaye lẹkunrẹrẹ nipa won ni ẹkọ yii jẹ. Iwo naa le ri ifarahan awon ẹbun yii ninu aye rẹ.
Pataki Ajinde Jesu Oluwa fun gbogbo eniyan
Bi o ti wu ki nkan le to ni orileede aye lonii, Ọrọ Ọlọrun ko le yẹ, ko si le yipada. Ninu ẹkọ yii, a o ri alaye nipa bi a se le duro lori oun ti Ọlọrun ti so nipa wa ninu Ọrọ Rẹ, bi a ba tile nkoju isoro ninu aye yii
Ẹkọ pataki fun gbogbo Oluka Bibeli, paapaa julọ awọn iranṣẹ Ọlọrun
Orukọ Jesu ni aṣẹ ti a ni gẹgẹ bi Onigbagbọ lati beere ohunkohun lọwọ Ọlọrun tabi lati paṣẹ ohun ti a ba fe ninu aye yii
Jesu Olugbala ni Onisegun nla. Ife Ọlọrun nigbagbogbo ati fun gbogbo eniyan si ni iwosan. Ẹkọ nipa bi o se le gba iwosan fun ara rẹ tabi fun ẹlomiran leleyii
Ẹkọ pataki nipa iye ainipẹkun ti Jesu Oluwa fifun gbogbo onigbagbọ (Johannu 3:16)
Gbogbo ọmọ Ọlọrun lo pon dandan fun lati gbe igbe aye iwamimọ. Sugbọn iyatọ gedegbe lo wa laarin Isọdimimọ ati Iwa Mimọ. Meejeji la ṣalaye ninu ẹkọ yii.
Ododo Ọlọrun yatọ si ti eniyan. Ẹkọ yii tan imọle si bi Ọlọrun Olododo ṣe ma n da eniyan lare
Njẹ mo ni lati jẹwọ ẹṣẹ mi fun Ọlọrun lati di eni igbala tabi lati gba idariji ẹṣẹ lọwọ Ọlọrun lẹyin igba ti mo ti di ẹni igbala tan? Ẹkunrẹrẹ alaye lori oun ti Bibeli so nipa Ijẹwọ Ẹṣẹ ni ẹkọ yii jẹ.
Nje agbara mbẹ ninu ẹjẹ Jesu bi? Ki tilẹ ni agbara yii gangan? Ati pe kini itumo ẹjẹ Jesu?
Awọn Ibukun kan wa ti Ọlọrun ti pese fun gbogbo awon ọmọ Rẹ.